Nitori aye — eda gbagbe Olorun
Nitori aye — eeyan gbagbe iku o
Aye yi, aye eh — aye eh eh ah ah ah aye yi
Eniyan fe aye, aye o feran won
Won ni aye n d’ogbo, aye o kuro, eniyan lo tun s’aye di tuntun
Aye ja gba lowo eeyan o fi tun 'ra e se, eda o mo ja gba lowo aye k’on fi
t’orun won se
Eda gbagbe oh eh, eniyan gbagbe o
P’aye yii kii se t’eniyan
Eda wa na’ja laye ni
Aye aye (Aye e e o o o o)
This world eeh (hmn hmn hmn hmn oh this world, aye yi)
Ara ki lo n wa, t’o n wa to bee t’o n sa kijo kijo
Ore ki lohun to mu wa, t’o fe di pada lo, tell me I want to know
Aye n w’owo, tori e pa’ra won lekun, ah o se
Tori ile, tori aso, alumoni oro repete, eniyan tori agbara di kiniun,
ikoko ajorijapa
Won a ma bu ramuramu, a di iduro o si, ibere o si o, bi eni to gb’odo mi
Aye aye (Aye e e o o o o)
This world eeh (hmn hmn hmn hmn oh this world, aye yi)
Eniyan lo n p’aye, aye o p’eeyan
Eda n fe’fun p’aye, aye o se kirakita
Aye o se wahala (En)
Eniyan lo n wo laasigbo (Oin)
S’enu jeje mu’ti laye (En)
Aye o lese, aye mirin (Oin)
Eniyan n ro lese tori aye (En)
Aye o loju, aye n riran (Oin)
Oju eda n wa’mi tori aye (En)
Aye logba eniyan lo n ro’ko e (Oin)
Aye o loyun, aye n bimo (En)
Omo t’eniyan n bi, aye tun n ni won (Oin)
Eniyan o gbon mo pa’ye n pamo o ki iku to de
La i lojo lori eniyan n gbo
Aye f’arungbo ojo ori eeyan, eda lo n sise oro f’aye, t’aye fi n tuntun si
lojoojo
Aye d’oloro, eniyan n ku 'ku otosi
Aye de gbon 'gbon akuusin
Aye aye (Aye e e o o o o)
This world eeh (hmn hmn hmn hmn oh this world, aye yi)
Eniyan ronu o, k’aye to je o mo orun re
Omo to so 'le nu, n lo so apo iya ko
Olugbala ke tantan o, omo maa bo
Oga ogo feran re o, omo yara wa
Ara ma ko 'fe Jesu yi o, wa gba 'rapada to f’eje se
This is practical love that I’ve ever seen in display
Aye aye (Aye e e o o o o)
This world eeh (hmn hmn hmn hmn oh this world, aye yi)
Ife amutorunwa, igbala yi On lo le se
Ona isinmi miran ko si, afi ninu ife Oluwa
Ko s’eni to le fe o to Jesu
Ultimate price He has paid
Pansaga, agbere wa, ole, ika, e yara wa
Apanilekun e sare ma bo
Iborisa at’akogun ja 'lu
Eyin akogun ja orile ede
E gb’ohun Eleda yin, t’On f’ife pe yin o
Ore ma d’aniyan si, ko ma so p’oo gbo
O n pe o, omo wa gba 'gbala
S’e ti r’alaso to ku ti won d’aso e mo (E je n gbo)
S’e ti r’eleran to ku ti won di maalu mo (Aye e gbo)
Onipetesi wo lo ku, ti won di’le e mo (K'e je a gbo)
Aye agbara n f’alagbara sile, ogun a di t’awon to le jagun
Oro a di t’awon ti o mo’di oro, ma fi 'gbala re sofo
Aye aye (Aye e e o o o o)
This world eeh (hmn hmn hmn hmn oh this world, aye yi)
Aye aye (Aye e e o o o o)
This world eeh (hmn hmn hmn hmn oh this world, aye yi)